-
1.1K Views
0 Comments
0 Likes
0 Reviews
Iléeṣé Ọlọ́pàá ẹ̀ka ti Ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun ti fọwọ́ ṣìkún òfin mú ọ̀kan láraawọn, Sájẹ́ńtì Ọnatunde Jọba tí fọ́nrán amóhùnmáwòrán rẹ̀ tàn kán orí ẹ̀rọ ayélujára láìpẹ́ yí tó ṣàfihàn rẹ̀ gẹ́gẹ́bí ẹni tó ti mutíyó tí ó sì ń ṣe kántan-kàntan kiri.
Alukoro Ọlọ́pàá Ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun SP Yemisi Opalola ṣàlàyé wípé iléeṣé Ọlọ́pàá ò ní fààyè gba irúfẹ́ ìwà àìlójútì bẹ́ẹ̀ látọ̀dọ̀ ẹnikẹ́ni tí ó bá jẹ́ òṣìṣẹ́ rẹ nítorí ìwà àti ìṣe tó ǹ tàbùkù iṣẹ́ agbófinró ni.
Ó ṣàfikún ọ̀rọ̀ rẹ wípé, gbogbo ìwádìí tó lẹtọ ni wọ́n ń ṣe lọ́wọ́ nípa arákùnrin Ọlọ́pàá náà láti lè mọ ohun tó rí lọ́bẹ̀ tófi waaro ọwọ́ nípa mímu ọtí yó pẹ̀lú aṣọ Ọlọ́pàá lọrun rẹ leyi tó ṣàtakò si òfin tó ṣàgbéró iṣẹ́ rẹ̀. Àtipé òun fúnraarẹ̀ ti wà lọ́wọ́ àwọn ìgbìmọ̀ oluwadi ẹni lẹka isẹ Ọlọ́pàá láti bá a ṣẹjọ́.
Àtẹ̀jáde ọ̀rọ̀ rẹ lọ báyìí pé :
"iléeṣé Ọlọ́pàá ti Ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun ti gbìnàyá lórí ọ̀rọ̀ arákùnrin agbófinró kan tórúkọ rẹ ń jẹ Sgt Ọnatunde Jọba tí fọ́nrán amóhùnmáwòrán rẹ gba ojú òpó ayélujára kan láìpẹ́ yí tó ṣàfihàn rẹ wípé ó mu ọtí yo tó sì ń ṣe kántan-kàntan kiri. A fi ń dáayín lójú pé iléeṣé Ọlọ́pàá ò ní fààyè gba irúfẹ́ ìwà jákujàku bẹẹ, àti pé, wọn tí fọwọ́ọ ṣìkún òfin múu, ó sì wà ní àhámọ́ báyìí fún ìwà ìdójútì tí ó hu yí."
Bakanna ni Kọmíṣọ́nà Ọlọ́pàá Ìpínlẹ̀ òhun CP Olawale Olokode náà ṣàlàyé wípé iléeṣé Ọlọ́pàá o níí fààyè gba ẹnikẹ́ni láti tàbùkù iṣẹ́ náà. Àtipé ìjìyà tí ó bá tọ́sí arákùnrin náà ni wọn o fi jẹ ẹ lábẹ́ òfin nítorí kí ó lè ba à jẹ́ ẹ̀kọ́ fún ẹnikẹ́ni tí ó bá tún fẹ́ẹ́ hu irú Ìwà bẹ́ẹ̀.
Share this page with your family and friends.