-
1K Views
0 Comments
2 Likes
0 Reviews
ILÉEṢÉ ỌMỌ OGUN ILẸ̀ẸWA Ò FÌYÀ JẸ ỌMỌBÌNRIN NÁÀ RÁRÁ O, A KÀN FI PAMỌ́ SÍ YÀRÁ ÀWỌN ALÁÌGBỌRÀN NI.
Látàrí awuyewuye kan tó ń lọ lọ́wọ́ lórí ẹ̀rọ ayélujára lákòókò yí nípa pé àwọn ológun ilẹ̀ yí ti ń fìyà pá ọmọbìnrin ọmọ ogun ilẹ̀ẹwa kan tí fọ́nrán amóhùnmáwòrán rẹ̀ gba orí ẹ̀rọ ayélujára kan láìpẹ́ yí níbi tí ọmọkùnrin olùsìnrúìlú kan ti ń fún un ní òrùka Ìfẹ́ láti fi sààmì èdìdí Ìfẹ́ rẹ̀ síi láti lè jẹ́ ìyàwó àfẹ́sọ́nà rẹ ló mú kí iléeṣẹ́ ológun ilẹ̀ wa o tètè sọ̀rọ̀ jáde wípé, ọ̀rọ̀ ò rí bẹ́ẹ̀ rárá. Wọ́n ní lóòótọ́ lọmọbìnrin ọ̀hún tàpá sí òfin àwọn ológun ilẹ̀ yí látàrí ìwà tí ó hù náà, àmọ́ kì í ṣe pé àwọn fọwọ́ ṣìkún òfin mú u láti fìyà jẹ ẹ́, bíkòṣe láti fi sí yàrá àhámọ́ àwọn aláìgbọràn lójúnà àti fi kọ́ọ lẹko akìíṣebẹ́ẹ̀ nítorí ọjọ́ min in.
Nínú fọ́nrán ọ̀hún ni ọ̀pọ̀ àwọn olùsìnrúìlú ti ń fi ìdùnnú hàn bí arákùnrin olùsìnrúìlú náà ṣe ń fòrùka sọ̀wọ́ obìnrin ọmọ ogun ilẹ̀ẹwa náà tí ó jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn alábòójútó àwọn olùsìnrúìlú ọ̀hún pẹ̀lú aṣọ ọmọ ogun ilẹ̀ẹwa lọ́rùn un rẹ̀ nígbà tí ọkùnrin náà sì dé fìlà obìnrin ọmọ ogun ọ̀hún.
Iléeṣẹ́ ológun ilẹ̀ẹwa ṣe é lálàyé wípé, obìnrin ọmọ ogun ilẹ̀ẹwa wa yí ò tí ì yẹ lẹ́ni tó yẹ kó ṣerú ǹkan bẹ́ẹ̀ lábẹ́ òfin tó ṣàgbéró iṣẹ́ ológun ilẹ̀ẹwa. Àtipé kò yẹ kójẹ́pé nínú ọgbà ìfojúẹnimọlé ló yẹ kírúfẹ́ ǹkan bẹ́ẹ̀ ti wáyé pẹ̀lú aṣọ ogun lọ́rùn un rẹ̀. Wọ́n ní kábání kì í ṣe pé ìṣẹ̀lẹ̀ náà ṣẹ̀ níbi tó ti wáyé ni, kò sẹ́ni tó máa rí tàwọn méjèèjì rò rárá.
Wọ́n tún wáá ṣe é lálàyé pé ìfọwọ́ ṣìkún òfin mú ọmọbìnrin náà jù sínú yàrá àhámọ́ àwọn aláìgbọràn kòju wípé kó lè baàjẹ́ ẹ̀kọ́ fún ẹlòmíràn nínú ọmọ ogun ilẹ̀ẹwa lóbìnrin láti má le hu irú ìwà bẹ́ẹ̀ lọ́jọ́ iwájú tàbí hù èyí tí ó burú jùbẹ́ẹ̀lọ.
Share this page with your family and friends.