-
3.6K Views
0 Comments
0 Likes
0 Reviews
Láìpẹ́ yí ni ìròyìn kan gbàgboro kan wípé wọ́n jí òǹdíjedupò gómìnà ní Ìpínlẹ̀ Imo lábẹ́ àsíá ẹgbẹ́ òṣèlú Action Alliance (AA) Olóyè Uche Nwosu lọ́dún 2019 gbé nílé ìjọsìn kan lọ́jọ́ àìkú tó kọjá yí, àmọ́ tó jẹ́ pé àwọn ọlọ́pàá ọ̀tẹtẹ̀múyẹ́ ilẹ̀ẹwa tètè yára tako ìròyìn náà wípé àwọn làwọn fi ọwọ́ ṣìkún òfin múu kì í ṣe àwọn ajínigbé gẹ́gẹ́bí ìròyìn tó gbàgboro kan.
Olóyè Uche Nwosu òun fúnraarẹ̀ ti wá ṣàlàyé àwọn ọ̀rọ̀ kan lórí ìṣẹ̀lẹ̀ ọ̀hún àti ohun tí ojú rẹ̀ rí lọ́wọ́ àwọn ọlọ́pàá tí wọ́n lọ gbée nílé ìjọsìn ọ̀hún.
Ó ṣàlàyé wípé ẹ̀sùn tí òun ò mọ ǹkankan nípa rẹ̀ rárá ni Wọ́n kà sí òun lẹ́sẹ́ nípa pé òun ń ṣagbódegbà kíkó ohun ìjà fún àwọn ajìjàngbara àti onígbọ̀wọ́ fún ìmẹ́hẹ ètò ààbò ní Ìpínlẹ̀ Imo.
Ó ní ó jé ohun ìbanilórúkọjẹ́ gbáà láti lè dárú aṣọ bẹ́ẹ̀ ró f'óun. Àtipé òun rọ gíwá àwọn ọlọ́pàá nílè yí, Alkali Usman láti ṣe ìwádìí ìjìnlẹ̀ lórí ẹ̀sùn náà àti ìhùwàsí àwọn ọlọ́pàá ẹ̀ka tí wọ́n wáá gbé òun nílé ìjọsìn náà.Ó sọ̀rọ̀ yí lọ́jọ́ Ajé tó lọ fún àwọn oníròyìn wípé, ìṣọwọ́ dúnkookò mọ́ òun lọ́jọ́ náà kì í ṣe ǹkan kékeré rárá nítorí àwọn ọlọ́pàá náà ń sọ fún òun wípé níṣeni àwọn máa fi ìbọn fọ́ orí òun yángá bí òun bá le kùnà láti má lè jẹ́ kí àwọn ó fọwọ́ ṣìkún òfin mú òun lẹ́rọ̀.
Lákòókò tí wọ́n ń ṣe ẹ̀yẹ̀ ìkẹyìn fún ìyá rẹ tó dolóògbé, Jemamah Nwosu ní ilé ìjọsìn St. Peter's Anglican, tówàní Eziama-Obaire ní Ìjọba ìbílẹ̀ Nkwerre Ìpínlẹ̀ Imo ni ìṣẹ̀lẹ̀ òhun wáyé.
Kódà, ìṣẹ̀lẹ̀ náà ló fa aáwọ̀ ìtahùn síraaẹni láàárín aṣòfin tó ń ṣojú fún ìwọ̀ oòrùn Ìpínlẹ̀ Imo nílé ìgbìmọ̀ aṣòfin ilẹ̀ẹwa, Owelle Rochas Okorocha àti Ìjọba Ìpínlẹ̀ Imo.
Nwosu jẹ́ ọkọ ọmọ Rochas Okorocha, ó sì ṣàlàyé pé, iléeṣẹ́ ọlọ́pàá abẹ́nú tí wọ́n gbé òun lọ lòun ti ríigbọ́ wípé ènìyàn kan ló kọ̀wé ẹ̀sùn takò'un wípé òun ń kó àwọn ohun ìjà fún àwọn ajìjàngbara.
Ó ní : "inú mi dùn fún ìgbésẹ̀ tí gíwá àwọn ọlọ́pàá ilẹ̀ yí gbé lórí ọ̀rọ̀ yí, pẹ̀lú ìṣe ìwádìí tí wọ́n ṣe láti lè fìdí ẹ̀rí rẹ múlẹ̀ wípé n ò lẹ́bọ lẹ́rù leyi tí ó ṣokùnfà yíyàǹda mi.
" àmọ́ n ó rọ gíwá àwọn ọlọ́pàá lẹ́ẹ̀kan síi wípé kí wọn ó ṣàyẹ̀wò ìhùwàsí àwọn ọlọ́pàá Ìpínlẹ̀ Imo nítorí wípé ọ̀pọ̀ aláìṣẹ̀ nirúfẹ́ ǹkan báyìí ń ṣẹlẹ̀ sí tí wọn kì í rẹ́ni jà fúnwọn. Bí kì í bá ṣe pé ó jẹ́ èmi ni, Ọlọ́hun nìkan ló mọ ohun tí kìbá ṣẹlẹ̀. Mi ò jà fúnraàmi o, àmọ́ fún ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀dọ́ wa gbogbo tó wà káàkiri tí wọn ò lẹ́nìkan tólẹ̀ jà fún wọn bírú ǹkan bẹ́ẹ̀ bá ṣẹlẹ̀. "
" Wọ́n ṣemí ṣákaṣàka, èdè Hausa ni wọ́n ń sọ síraawọn. Kódà, wón pe ẹnikan tí ó jé olórí àwọn èṣọ́ aláàbò tó ń jẹ Shaba wípé ọwọ́ ti tẹ̀ mí láláìmọ̀ wípé mo gbọ́ èdè tí wọ́n ń sọ.
Ọ̀kan nínú àwọn bí i mẹẹdogun tí wọ́n daṣo bojú ọ̀hún paalaṣẹ fúnmi wípé kí n sùn sílẹ̀ gbalaja, ó sì gbé ẹsẹ̀ rẹ lémi lórí.
Nígbà tí a dé ibìkan tí wọ́n ń pè ní Umuaka, wọn dúró níbè, mo ti ẹ̀ kọ́kọ́ rò wípé wọ́n fẹ́ẹ́ pami ni. Àmọ́ nisẹ ni wọn pàṣẹ kí n bọ́ aṣọ mi. Wọ́n fi ẹ̀wọ̀n simi lọ́wọ́, wọn sì bẹ̀rẹ̀ sí ní ṣe àkáálẹ̀ mi sórí ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀ èyí tí fi ráńṣẹ́ sí ẹni tí ó jé olórí àwọn ẹ̀ṣọ́ aláàbò. Lẹ́yìn náà, wọ́n pààrọ̀ ọkọ̀, a sì tẹ síwájú.
Àmọ́ nínú ọ̀rọ̀ tí Rochas Okorocha, ó ní Ìpínlẹ̀ Imo lọ́wọ́ yí ti di ìpínlè tí àwọn ènìyàn ibè ń gbé nínú ìpayà.
Àwọn Ẹgbẹ́ CAN pàápàá bu ẹnu àtẹ́ lu ìhùwàsí àwọn ọlọ́pàá náà wípé ó kù díè kaato láti lè deruba àwọn ènìyàn lákòókò ìjọsìn.
Àwọn IPOB pàápàá sọ wípé, ìwádìí tí jẹ ki wọn o mọ wípé arakunrin Uche Nwosu o mọ ńkankan nipa ẹ̀sùn tí wọ́n fi kan an náà.
Òun fúnraarẹ̀ sì ṣàlàyé wípé, pẹ̀lú bí gbogbo rẹ ti rí yí, òun ò níí kó àárẹ̀ ọkán rárá lagbo oselu, nítorí òun rí i bí i ìdúnkookò mọ́ni lásán ni.
Share this page with your family and friends.